Oloye Elizabeth Ibidun MORAFA
O digba kan na!
Okiki gboo! Ariwo yaan!! Kini o sele t'ariwo fi po bawon yi?
Iya Oninure lolo lai boju wehin; Iya Alanu re ibiti awon agba nree.
Sebi o wuni ki ajeran pe lenu, sugbon ounfa ona ofun ni koje. Iya wa Iya gbogbo aye, onisuru atata, Alabaro, Olubanidamoran, Iya okunrin, Iya obinrin, Iya kekere, Iya agbalagba, Iya nile, Iya lode, Iya loja!
Olubanikedun, Abiwa pele.
Ko yami lenu rara pee gbogbo wa lonse idaro Agba Agbeluniyi ti ile Egbe;
A dupe lowo Olodumare, E wo iye opo omo ti Iya bi -- Meji lo ti nu wa, aimoye omo ati omoomo ti ko lohunka, nile, loko ati lehin odi. Gbogbo won lo fowo le owo Iya wa oloye Ibidun. Egbe ni o, Ilorin Afonja ni o, Eko ni o abi Ibadan, Igbaja ati Okun, Iya wa amayerorun ni ilu awon abara funfun:
Gbogbo omo ti o ba ti sipa ni Iya Elizabeth a gbemora tipetipe!
Orun rere o, Ogbontarigi ninu olokowo;
Iya fanu le omo lowo, Iya finu rere to omo beni ko si alabuku ninu awon arole ti o fi sile.
O digbose iya wa. O di arinnako, o di oju ala, o tun dola. A o pade lese Jesu
Akanjis